10 torí a ti gbọ́ bí Jèhófà ṣe mú kí omi Òkun Pupa gbẹ níwájú yín nígbà tí ẹ kúrò ní Íjíbítì+ àti ohun tí ẹ ṣe sí àwọn ọba Ámórì méjèèjì, ìyẹn Síhónì+ àti Ógù+ tí ẹ pa run ní òdìkejì* Jọ́dánì.
5Gbàrà tí gbogbo ọba àwọn Ámórì,+ tí wọ́n wà lápá ìwọ̀ oòrùn* Jọ́dánì àti gbogbo ọba àwọn ọmọ Kénáánì,+ tí wọ́n wà létí òkun gbọ́ pé Jèhófà ti mú kí omi Jọ́dánì gbẹ níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí wọ́n fi sọdá, ọkàn wọn domi,*+ kò sì sí ẹni tó ní ìgboyà mọ́* torí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+