ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 23:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 “Kí o mú èyí tó dáa jù nínú àwọn èso tó kọ́kọ́ pọ́n ní ilẹ̀ rẹ wá sí ilé Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+

      “O ò gbọ́dọ̀ se ọmọ ewúrẹ́ nínú wàrà ìyá rẹ̀.+

  • Léfítíkù 2:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 “‘Tí o bá fẹ́ ṣe ọrẹ ọkà àkọ́pọ́n èso rẹ fún Jèhófà, ọkà tuntun* tí o yan lórí iná ni kí o mú wá, kóró tuntun tí o kò lọ̀ kúnná, kí o fi ṣe ọrẹ ọkà àkọ́pọ́n èso+ rẹ.

  • Nọ́ńbà 18:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Jèhófà tún sọ fún Áárónì pé: “Èmi fúnra mi fi gbogbo ọrẹ tí wọ́n bá ṣe fún mi+ sí ìkáwọ́ rẹ. Mo ti fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lára gbogbo ohun mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá fi ṣe ọrẹ, kó jẹ́ ìpín+ yín títí lọ.

  • Nọ́ńbà 18:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 “Mo fún ọ+ ní gbogbo òróró tó dáa jù àti gbogbo wáìnì tuntun tó dáa jù àti ọkà, àkọ́so+ wọn, èyí tí wọ́n fún Jèhófà.

  • Diutarónómì 26:1, 2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 26 “Tí o bá wá dé ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ pé kí o jogún, tí o ti gbà á, tí o sì ti ń gbé ibẹ̀, 2 kí o mú lára gbogbo ohun* tó bá kọ́kọ́ so ní ilẹ̀ náà, èyí tí o bá kó jọ ní ilẹ̀ rẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ, kí o kó o sínú apẹ̀rẹ̀, kí o sì lọ sí ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá yàn pé kí orúkọ rẹ̀ máa wà.+

  • Òwe 3:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  9 Fi àwọn ohun ìní rẹ tó níye lórí bọlá fún Jèhófà,+

      Pẹ̀lú àkọ́so* gbogbo irè oko rẹ;*+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́