- 
	                        
            
            Ẹ́kísódù 14:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        11 Wọ́n sọ fún Mósè pé: “Ṣé torí kò sí ibi ìsìnkú ní Íjíbítì lo ṣe mú wa wá sínú aginjù ká lè kú síbí?+ Kí ló dé tí o mú wa kúrò ní Íjíbítì? 
 
- 
                                        
- 
	                        
            
            Ẹ́kísódù 17:3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        3 Síbẹ̀ òùngbẹ ń gbẹ àwọn èèyàn náà gan-an níbẹ̀, wọ́n sì ń kùn sí Mósè ṣáá,+ wọ́n ń sọ pé: “Kí ló dé tí o mú wa kúrò ní Íjíbítì kí o lè fi òùngbẹ pa àwa àti àwọn ọmọ wa àti àwọn ẹran ọ̀sìn wa?” 
 
- 
                                        
- 
	                        
            
            Nọ́ńbà 16:13, 14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        13 Ṣé ohun kékeré lo rò pé o ṣe, bí o ṣe mú wa kúrò ní ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn, kí o lè wá pa wá sínú aginjù?+ Ṣé o tún wá fẹ́ sọ ara rẹ di ọba* lé wa lórí ni? 14 Títí di báyìí, o ò tíì mú wa dé ilẹ̀ kankan tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn,+ bẹ́ẹ̀ lo ò fún wa ní ilẹ̀ àti ọgbà àjàrà kankan láti jogún. Ṣé o fẹ́ yọ ojú àwọn èèyàn yẹn ni? A ò ní wá!” 
 
-