-
Nehemáyà 9:19, 20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 síbẹ̀ ìwọ, nínú àánú ńlá rẹ, o ò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ nínú aginjù.+ Ọwọ̀n ìkùukùu* kò kúrò lórí wọn ní ọ̀sán láti máa darí wọn ní ọ̀nà wọn, ọwọ̀n iná* kò sì kúrò ní òru láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀nà tí wọ́n máa gbà.+ 20 O fún wọn ní ẹ̀mí rere rẹ láti jẹ́ kí wọ́n ní ìjìnlẹ̀ òye,+ o ò fawọ́ mánà rẹ sẹ́yìn kúrò ní ẹnu wọn,+ o sì fún wọn ní omi nígbà tí òùngbẹ ń gbẹ wọ́n.+
-