13 Tí o bá ti rí i, a máa kó ọ jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ,+ bíi ti Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ,+ 14 torí nígbà tí àpéjọ náà ń bá mi jà ní aginjù Síínì, ẹ ṣe ohun tó lòdì sí àṣẹ tí mo pa pé kí ẹ tipasẹ̀ omi+ náà fi hàn pé mo jẹ́ mímọ́ níṣojú wọn. Èyí ni omi Mẹ́ríbà+ tó wà ní Kádéṣì + ní aginjù Síínì.”+