-
Jóṣúà 8:33, 34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
33 Gbogbo Ísírẹ́lì, àwọn àgbààgbà wọn, àwọn olórí àtàwọn adájọ́ wọn dúró sí ẹ̀gbẹ́ méjèèjì Àpótí náà, níwájú àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì, tí wọ́n ń gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà. Àwọn àjèjì àtàwọn ọmọ ìbílẹ̀ náà wà níbẹ̀.+ Ìdajì wọn dúró síwájú Òkè Gérísímù, ìdajì tó kù sì wà níwàjú Òkè Ébálì+ (bí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe pa á láṣẹ tẹ́lẹ̀),+ láti súre fún àwọn èèyàn Ísírẹ́lì. 34 Lẹ́yìn náà, ó ka gbogbo ọ̀rọ̀ inú Òfin+ náà sókè, àwọn ìbùkún+ àti àwọn ègún+ tó wà nínú rẹ̀, bí wọ́n ṣe kọ gbogbo rẹ̀ sínú ìwé Òfin náà.
-