ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 15:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Kí o lawọ́ sí i dáadáa,+ kí o* má sì ráhùn tí o bá ń fún un, torí èyí á mú kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe àtàwọn ohun tí o bá dáwọ́ lé.+

  • Sáàmù 41:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 41 Aláyọ̀ ni ẹni tó bá ń ro ti àwọn aláìní;+

      Jèhófà yóò gbà á sílẹ̀ ní ọjọ́ àjálù.

  • Òwe 11:24
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 Ẹnì kan wà tó ń fúnni lọ́pọ̀lọpọ̀,* ó sì ń ní sí i;+

      Ẹnì kan sì wà tó ń fawọ́ ohun tó yẹ kó fúnni sẹ́yìn, àmọ́ ó di aláìní.+

  • Òwe 19:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Ẹni tó ń ṣojúure sí aláìní, Jèhófà ló ń yá ní nǹkan,+

      Á sì san án* pa dà fún un nítorí ohun tó ṣe.+

  • Málákì 3:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Ẹ mú gbogbo ìdá mẹ́wàá wá sínú ilé ìkẹ́rùsí,+ kí oúnjẹ lè wà nínú ilé mi.+ Ẹ jọ̀ọ́, ẹ fi èyí dán mi wò,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí, “kí ẹ lè rí i bóyá mi ò ní ṣí ibú omi ọ̀run,+ kí n sì tú* ìbùkún sórí yín títí ẹ kò fi ní ṣaláìní ohunkóhun.”+

  • Lúùkù 6:35
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 35 Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín, ẹ máa ṣe rere, kí ẹ sì máa yáni ní nǹkan láìretí ohunkóhun pa dà;+ èrè yín máa wá pọ̀, ẹ sì máa jẹ́ ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ, torí ó máa ń ṣoore fún àwọn aláìmoore àti àwọn ẹni burúkú.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́