ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 25:35
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 35 “‘Tí arákùnrin rẹ tó wà nítòsí bá di aláìní, tí kò sì lè bójú tó ara rẹ̀, kí o ràn án lọ́wọ́+ bí o ṣe máa ṣe fún àjèjì àti àlejò,+ kó lè máa wà láàyè pẹ̀lú rẹ.

  • Òwe 19:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Ẹni tó ń ṣojúure sí aláìní, Jèhófà ló ń yá ní nǹkan,+

      Á sì san án* pa dà fún un nítorí ohun tó ṣe.+

  • Mátíù 5:42
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 42 Tí ẹnì kan bá ń béèrè nǹkan lọ́wọ́ rẹ, fún un, má sì yíjú kúrò lọ́dọ̀ ẹni tó fẹ́ yá nǹkan* lọ́wọ́ rẹ.+

  • Lúùkù 6:34, 35
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 34 Bákan náà, tí ẹ bá ń yá* àwọn tí ẹ retí pé wọ́n máa san án pa dà ní nǹkan, àǹfààní kí ló jẹ́ fún yín?+ Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá máa ń yá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní nǹkan kí wọ́n lè rí ohun kan náà gbà pa dà. 35 Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín, ẹ máa ṣe rere, kí ẹ sì máa yáni ní nǹkan láìretí ohunkóhun pa dà;+ èrè yín máa wá pọ̀, ẹ sì máa jẹ́ ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ, torí ó máa ń ṣoore fún àwọn aláìmoore àti àwọn ẹni burúkú.+

  • Gálátíà 2:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Ohun kan ṣoṣo tí wọ́n béèrè ni pé kí a fi àwọn aláìní sọ́kàn, mo sì ń sapá gan-an láti ṣe bẹ́ẹ̀.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́