Diutarónómì 8:5 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 5 O mọ̀ dáadáa lọ́kàn rẹ pé bí bàbá ṣe ń tọ́ ọmọ rẹ̀ sọ́nà ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń tọ́ ọ sọ́nà.+ Òwe 13:24 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 24 Ẹni tó bá fa ọ̀pá* sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀,+Àmọ́ ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀ máa ń bá a wí dáadáa.*+ Òwe 19:18 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 18 Bá ọmọ rẹ wí nígbà tí ìrètí ṣì wà,+Kí o má bàa jẹ̀bi* ikú rẹ̀.+ Òwe 23:13 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 13 Má fawọ́ ìbáwí sẹ́yìn fún ọmọdé.*+ Tí o bá fi ọ̀pá nà án, kò ní kú. Hébérù 12:9 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 9 Bákan náà, àwọn bàbá tó bí wa* máa ń bá wa wí, a sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn. Ṣé kò wá yẹ kó yá wa lára láti fi ara wa sábẹ́ Baba tó ni ìgbésí ayé wa nípa ti ẹ̀mí, ká lè máa wà láàyè?+
9 Bákan náà, àwọn bàbá tó bí wa* máa ń bá wa wí, a sì máa ń bọ̀wọ̀ fún wọn. Ṣé kò wá yẹ kó yá wa lára láti fi ara wa sábẹ́ Baba tó ni ìgbésí ayé wa nípa ti ẹ̀mí, ká lè máa wà láàyè?+