-
1 Àwọn Ọba 1:5, 6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Ní àkókò yìí, Ádóníjà+ ọmọkùnrin Hágítì ń gbé ara rẹ̀ ga, ó ń sọ pé: “Èmi ló máa di ọba!” Ó ní kí wọ́n ṣe kẹ̀kẹ́ ẹṣin kan fún òun, ó kó àwọn agẹṣin jọ àti àádọ́ta (50) ọkùnrin tí á máa sáré níwájú rẹ̀.+ 6 Àmọ́ bàbá rẹ̀ kò bi í* pé: “Kí nìdí tí o fi ṣe báyìí?” Òun náà lẹ́wà gan-an, ìyá rẹ̀ sì bí i lẹ́yìn tí wọ́n bí Ábúsálómù.
-