4 Kí ààlà yín sì yí gba gúúsù, kó gba ibi tí wọ́n ń gbà gòkè ní Ákírábímù+ títí lọ dé Síínì, kó sì parí sí gúúsù Kadeṣi-báníà.+ Kó wá dé Hasari-ádáárì+ títí lọ dé Ásímónì.
23 Nígbà tí Jèhófà ní kí ẹ lọ láti Kadeṣi-bánéà,+ tó sì sọ pé, ‘Ẹ gòkè lọ gba ilẹ̀ tó dájú pé màá fún yín!’ ẹ tún ṣe ohun tó lòdì sí àṣẹ tí Jèhófà Ọlọ́run yín pa,+ ẹ ò gbà á gbọ́,+ ẹ ò sì ṣègbọràn sí i.