ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Sámúẹ́lì 1:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Lọ́dọọdún, ọkùnrin yẹn máa ń lọ láti ìlú rẹ̀ sí Ṣílò+ láti jọ́sìn,* kó sì rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun. Ibẹ̀ ni àwọn ọmọkùnrin Élì méjèèjì, Hófínì àti Fíníhásì+ ti ń ṣe iṣẹ́ àlùfáà fún Jèhófà.+

  • 1 Sámúẹ́lì 4:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Nígbà tí àwọn èèyàn náà pa dà sí ibùdó, àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì sọ pé: “Kí ló dé tí Jèhófà fi jẹ́ kí àwọn Filísínì ṣẹ́gun wa lónìí?*+ Ẹ jẹ́ kí a lọ gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà láti Ṣílò,+ kí ó lè wà lọ́dọ̀ wa, kí ó sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa.”

  • Sáàmù 78:60
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 60 Níkẹyìn, ó pa àgọ́ ìjọsìn Ṣílò tì,+

      Àgọ́ tí ó gbé inú rẹ̀ láàárín àwọn èèyàn.+

  • Jeremáyà 7:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 “‘Àmọ́, ní báyìí ẹ lọ sí àyè mi ní Ṣílò,+ níbi tí mo mú kí orúkọ mi wà ní ìbẹ̀rẹ̀,+ kí ẹ sì wo ohun tí mo ṣe sí i nítorí ìwà búburú àwọn èèyàn mi, Ísírẹ́lì.+

  • Ìṣe 7:44, 45
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 44 “Àwọn baba ńlá wa ní àgọ́ ẹ̀rí nínú aginjù, bí Ọlọ́run ṣe pa á láṣẹ nígbà tó sọ fún Mósè pé kó ṣe é bí èyí tí ó rí.+ 45 Àwọn baba ńlá wa jogún rẹ̀, wọ́n sì gbé e wá nígbà tí wọ́n ń tẹ̀ lé Jóṣúà bọ̀ ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,+ àwọn tí Ọlọ́run lé jáde kúrò níwájú àwọn baba ńlá wa.+ Ó sì wà níbẹ̀ títí di ìgbà ayé Dáfídì.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́