-
Ẹ́kísódù 23:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 “Ẹ̀ẹ̀mẹta lọ́dún ni kí ẹ máa ṣe àjọyọ̀ fún mi.+
-
-
Diutarónómì 12:5, 6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Kàkà bẹ́ẹ̀, ibikíbi tí Jèhófà Ọlọ́run yín bá yàn pé kí orúkọ rẹ̀ wà àti ibi tó bá ń gbé láàárín gbogbo ẹ̀yà yín ni kí ẹ ti máa wá a, ibẹ̀ sì ni kí ẹ máa lọ.+ 6 Ibẹ̀ ni kí ẹ máa mú àwọn ẹbọ sísun yín wá+ àti àwọn ẹbọ yín, àwọn ìdá mẹ́wàá yín,+ ọrẹ látọwọ́ yín,+ àwọn ọrẹ tí ẹ jẹ́jẹ̀ẹ́, àwọn ọrẹ àtinúwá+ yín àti àwọn àkọ́bí ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran yín.+
-
-
Àwọn Onídàájọ́ 21:19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Wọ́n wá sọ pé: “Ẹ wò ó! Àjọyọ̀ Jèhófà tí a máa ń ṣe lọ́dọọdún máa wáyé ní Ṣílò,+ èyí tó wà ní àríwá Bẹ́tẹ́lì, lápá ìlà oòrùn ọ̀nà tó lọ láti Bẹ́tẹ́lì sí Ṣékémù àti gúúsù Lẹ́bónà.”
-