Ẹ́kísódù 15:11 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 11 Jèhófà, ta ló dà bí rẹ nínú àwọn ọlọ́run?+ Ta ló dà bí rẹ, ìwọ tí o fi hàn pé ẹni mímọ́ jù lọ ni ọ́?+ Ẹni tó yẹ ká máa bẹ̀rù, ká máa fi orin yìn, Ẹni tó ń ṣe ohun ìyanu.+ Diutarónómì 4:35 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 35 Ẹ̀yin fúnra yín ti rí nǹkan wọ̀nyí kí ẹ lè mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́;+ kò sí ẹlòmíì àfi òun nìkan.+ Sáàmù 73:25 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 25 Ta ni mo ní lọ́run? Lẹ́yìn rẹ, kò sí ohun míì tó wù mí ní ayé.+ Sáàmù 86:8 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 8 Jèhófà, kò sí èyí tó dà bí rẹ nínú àwọn ọlọ́run,+Kò sí iṣẹ́ kankan tó dà bíi tìrẹ.+ Sáàmù 89:6 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 6 Ta ló wà ní ọ̀run tí a lè fi wé Jèhófà?+ Èwo nínú àwọn ọmọ Ọlọ́run+ ló dà bíi Jèhófà?
11 Jèhófà, ta ló dà bí rẹ nínú àwọn ọlọ́run?+ Ta ló dà bí rẹ, ìwọ tí o fi hàn pé ẹni mímọ́ jù lọ ni ọ́?+ Ẹni tó yẹ ká máa bẹ̀rù, ká máa fi orin yìn, Ẹni tó ń ṣe ohun ìyanu.+
35 Ẹ̀yin fúnra yín ti rí nǹkan wọ̀nyí kí ẹ lè mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́;+ kò sí ẹlòmíì àfi òun nìkan.+