55 Gbàrà tí Sọ́ọ̀lù rí Dáfídì tó ń jáde lọ pàdé Filísínì náà, ó bi Ábínérì+ olórí ọmọ ogun pé: “Ábínérì, ọmọ ta ni ọmọdékùnrin yìí?”+ Ábínérì fèsì pé: “Bí o* ti wà láàyè, ìwọ ọba, mi ò mọ̀!”
27 Nígbà tí Ábínérì pa dà sí Hébúrónì,+ Jóábù mú un wọnú ibì kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnubodè láti bá a sọ̀rọ̀ ní ìdákọ́ńkọ́. Àmọ́, ibẹ̀ ni ó ti gún un ní ikùn, ó sì kú;+ èyí jẹ́ nítorí pé ó pa* Ásáhélì+ arákùnrin rẹ̀.