-
1 Sámúẹ́lì 14:50Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
50 Orúkọ ìyàwó rẹ̀ ni Áhínóámù ọmọ Áhímáásì. Orúkọ olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ni Ábínérì+ ọmọ Nérì tó jẹ́ arákùnrin bàbá Sọ́ọ̀lù.
-
-
2 Sámúẹ́lì 3:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Inú bí Ábínérì gan-an lórí ọ̀rọ̀ Íṣí-bóṣétì, ó sì sọ pé: “Ṣé ajá Júdà lo fi mí pè ni? Títí di òní yìí, mo ti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ilé Sọ́ọ̀lù bàbá rẹ àti sí àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, mi ò sì gbẹ̀yìn lọ fi ọ́ lé Dáfídì lọ́wọ́; síbẹ̀ lónìí, o pè mí wá jíhìn ẹ̀ṣẹ̀ nítorí obìnrin.
-