8 Màá lọ gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì,+ màá sì mú wọn kúrò ní ilẹ̀ yẹn lọ sí ilẹ̀ kan tó dára, tó sì fẹ̀, ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn,+ ní agbègbè àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì.+
5 Tí ẹ bá ṣègbọràn sí ohùn mi délẹ̀délẹ̀, tí ẹ sì pa májẹ̀mú mi mọ́, ó dájú pé ẹ ó di ohun ìní mi pàtàkì* nínú gbogbo èèyàn,+ torí gbogbo ayé jẹ́ tèmi.+