21 Áhítófẹ́lì wá sọ fún Ábúsálómù pé: “Bá àwọn wáhàrì* bàbá rẹ lò pọ̀,+ àwọn tó fi sílẹ̀ pé kí wọ́n máa tọ́jú ilé.*+ Gbogbo Ísírẹ́lì á wá gbọ́ pé o ti sọ ara rẹ di ẹni ìkórìíra lójú bàbá rẹ, ọkàn gbogbo àwọn tó ń tì ọ́ lẹ́yìn á sì balẹ̀.”
22 Ni Ọba Sólómọ́nì bá dá ìyá rẹ̀ lóhùn pé: “Kí ló dé tí o fi ní kí n fún Ádóníjà ní Ábíṣágì ará Ṣúnémù? Ò bá kúkú ní kí n fún un ní ìjọba pẹ̀lú+ nítorí pé ẹ̀gbọ́n mi ni,+ ẹ̀yìn rẹ̀ sì ni àlùfáà Ábíátárì àti Jóábù+ ọmọ Seruáyà+ wà.”