-
Diutarónómì 7:3, 4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 O ò gbọ́dọ̀ bá wọn dána rárá.* O ò gbọ́dọ̀ fi àwọn ọmọbìnrin rẹ fún àwọn ọmọkùnrin wọn, o ò sì gbọ́dọ̀ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin rẹ.+ 4 Torí wọn ò ní jẹ́ kí àwọn ọmọkùnrin rẹ tọ̀ mí lẹ́yìn mọ́, wọ́n á mú kí wọ́n máa sin àwọn ọlọ́run míì;+ Jèhófà máa wá bínú gidigidi sí ọ, kíákíá ló sì máa pa ọ́ run.+
-
-
Nehemáyà 13:25-27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Torí náà, mo bá wọn wí, mo sì gégùn-ún fún wọn, mo lu àwọn ọkùnrin kan lára wọn,+ mo fa irun wọn tu, mo sì mú kí wọ́n fi Ọlọ́run búra pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ fi àwọn ọmọbìnrin yín fún àwọn ọmọkùnrin wọn, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín tàbí fún ara yín.+ 26 Ṣé kì í ṣe tìtorí èyí ni Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì fi dẹ́ṣẹ̀? Kò sí ọba tó dà bíi rẹ̀ láàárín ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè;+ Ọlọ́run rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀+ débi pé ó fi í jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì. Síbẹ̀ àwọn àjèjì obìnrin tó fẹ́ mú òun pàápàá dẹ́ṣẹ̀.+ 27 Ṣé ó ṣeé gbọ́ sétí pé ẹ dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá yìí, tí ẹ hùwà àìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wa bí ẹ ṣe lọ ń fẹ́ àwọn àjèjì obìnrin?”+
-