ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 17:15, 16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 nígbà náà, kí o rí i dájú pé ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá yàn ni kí o fi jọba.+ Àárín àwọn arákùnrin rẹ ni kí o ti yan ẹni tó máa jọba. O ò gbọ́dọ̀ yan àjèjì, ẹni tí kì í ṣe arákùnrin rẹ ṣe olórí rẹ. 16 Àmọ́, kò gbọ́dọ̀ kó ẹṣin rẹpẹtẹ jọ fún ara rẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ ni kò gbọ́dọ̀ ní kí àwọn èèyàn náà pa dà lọ sí Íjíbítì láti lọ kó ẹṣin sí i wá,+ torí Jèhófà ti sọ fún yín pé, ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ tún forí lé ọ̀nà yìí mọ́.’

  • 1 Àwọn Ọba 10:24-26
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 Àwọn èèyàn láti ibi gbogbo láyé ń wá sọ́dọ̀* Sólómọ́nì kí wọ́n lè gbọ́ ọgbọ́n tí Ọlọ́run fi sí i lọ́kàn.+ 25 Kálukú wọn ń mú ẹ̀bùn wá, ìyẹn àwọn ohun èlò fàdákà, àwọn ohun èlò wúrà, àwọn aṣọ, ìhámọ́ra, òróró básámù, àwọn ẹṣin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,* wọ́n sì ń mú wọn wá lọ́dọọdún.

      26 Sólómọ́nì sì ń kó kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹṣin* jọ; ó ní ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (1,400) kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000) ẹṣin,*+ ó sì kó wọn sí àwọn ìlú kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti sí tòsí ọba ní Jerúsálẹ́mù.+

  • 2 Kíróníkà 1:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Sólómọ́nì ń kó kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹṣin jọ;* ó ní ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (1,400) kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000) ẹṣin,*+ ó sì kó wọn sí àwọn ìlú kẹ̀kẹ́ ẹṣin+ àti sí tòsí ọba ní Jerúsálẹ́mù.+

  • 2 Kíróníkà 1:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) fàdákà ni wọ́n ń ra kẹ̀kẹ́ ẹṣin kọ̀ọ̀kan láti Íjíbítì, àádọ́jọ (150) fàdákà sì ni wọ́n ń ra ẹṣin kọ̀ọ̀kan; wọ́n á wá fi wọ́n ránṣẹ́ sí gbogbo ọba àwọn ọmọ Hétì àti àwọn ọba Síríà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́