-
1 Àwọn Ọba 9:20-22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Ní ti gbogbo èèyàn tó ṣẹ́ kù lára àwọn Ámórì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì,+ tí wọn kì í ṣe ara àwọn èèyàn Ísírẹ́lì,+ 21 àwọn àtọmọdọ́mọ wọn tó ṣẹ́ kù sí ilẹ̀ náà, ìyẹn àwọn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò lè pa run, Sólómọ́nì ní kí wọ́n máa ṣíṣẹ́ fún òun bí ẹrú títí di òní yìí.+ 22 Àmọ́ Sólómọ́nì kò fi ọmọ Ísírẹ́lì kankan ṣe ẹrú,+ àwọn ló fi ṣe jagunjagun, ìránṣẹ́, ìjòyè, olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun, olórí àwọn tó ń gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ti àwọn agẹṣin rẹ̀.
-
-
2 Kíróníkà 2:17, 18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Sólómọ́nì wá ka gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì,+ lẹ́yìn ìkànìyàn tí Dáfídì bàbá rẹ̀ ṣe,+ iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ààbọ̀ ó lé ẹgbẹ̀rún mẹ́tà àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (153,600). 18 Nítorí náà, ó yan ọ̀kẹ́ mẹ́ta ààbọ̀ (70,000) lára wọn láti ṣe lébìrà* àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) láti máa gé òkúta+ ní àwọn òkè àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (3,600) láti ṣe alábòójútó tí á máa kó àwọn èèyàn ṣiṣẹ́.+
-
-
2 Kíróníkà 8:7-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Ní ti gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì,+ tí wọn kì í ṣe ara àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ 8 àwọn àtọmọdọ́mọ wọn tó ṣẹ́ kù sí ilẹ̀ náà, ìyẹn àwọn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò pa run,+ Sólómọ́nì ní kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ fún òun títí di òní yìí.+ 9 Àmọ́ Sólómọ́nì kò fi ọmọ Ísírẹ́lì kankan ṣe ẹrú fún iṣẹ́ rẹ̀,+ àwọn ló fi ṣe jagunjagun rẹ̀, olórí àwọn olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun rẹ̀, olórí àwọn tó ń gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ti àwọn agẹṣin rẹ̀.+
-