-
2 Kíróníkà 2:6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Ta ni agbára rẹ̀ gbé e láti kọ́ ilé fún un? Nítorí àwọn ọ̀run àti ọ̀run àwọn ọ̀run kò lè gbà á,+ ta wá ni mí tí màá fi kọ́ ilé fún un? Àfi kí n kàn kọ́ ọ gẹ́gẹ́ bí ibi tí a ó ti máa mú ẹbọ rú èéfín níwájú rẹ̀.
-
-
2 Kíróníkà 6:18-21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 “Àmọ́, ṣé Ọlọ́run á máa bá àwọn èèyàn gbé inú ayé ni?+ Wò ó! Àwọn ọ̀run, àní, ọ̀run àwọn ọ̀run, kò lè gbà ọ́;+ ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti ilé tí mo kọ́ yìí!+ 19 Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run mi, fiyè sí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ fún ojú rere, kí o sì fetí sí igbe ìránṣẹ́ rẹ fún ìrànlọ́wọ́ àti àdúrà tó ń gbà níwájú rẹ. 20 Kí ojú rẹ wà lára ilé yìí tọ̀sántòru, lára ibi tí o sọ pé wàá fi orúkọ rẹ sí,+ láti fetí sí àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà ní ìdojúkọ ibí yìí. 21 Kí o gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ fún ìrànlọ́wọ́ àti ẹ̀bẹ̀ àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n bá gbàdúrà ní ìdojúkọ ibí yìí,+ kí o gbọ́ láti ibi tí ò ń gbé, láti ọ̀run;+ kí o gbọ́, kí o sì dárí jì wọ́n.+
-