-
2 Kíróníkà 6:32, 33Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
32 “Bákan náà, ní ti àjèjì tí kì í ṣe ara àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì, àmọ́ tó wá láti ilẹ̀ tó jìnnà nítorí orúkọ ńlá rẹ*+ àti ọwọ́ agbára rẹ pẹ̀lú apá rẹ tó nà jáde, tí ó sì wá gbàdúrà ní ìdojúkọ ilé yìí,+ 33 nígbà náà, kí o fetí sílẹ̀ láti ọ̀run, ibi tí ò ń gbé, kí o sì ṣe gbogbo ohun tí àjèjì náà béèrè lọ́wọ́ rẹ, kí gbogbo aráyé lè mọ orúkọ rẹ,+ kí wọ́n sì máa bẹ̀rù rẹ, bí àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì ti ń ṣe, kí wọ́n sì mọ̀ pé a ti fi orúkọ rẹ pe ilé tí mo kọ́ yìí.
-
-
Àìsáyà 56:6, 7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Ní ti àwọn àjèjì tó fara mọ́ Jèhófà láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún un,
Láti nífẹ̀ẹ́ orúkọ Jèhófà,+
Kí wọ́n sì di ìránṣẹ́ rẹ̀,
Gbogbo àwọn tó ń pa Sábáàtì mọ́, tí wọn ò sì kẹ́gàn rẹ̀,
Tí wọ́n ń rọ̀ mọ́ májẹ̀mú mi,
7 Màá tún mú wọn wá sí òkè mímọ́ mi,+
Màá sì mú kí wọ́n máa yọ̀ nínú ilé àdúrà mi.
Màá tẹ́wọ́ gba odindi ẹbọ sísun wọn àtàwọn ẹbọ wọn lórí pẹpẹ mi.
Torí a ó máa pe ilé mi ní ilé àdúrà fún gbogbo èèyàn.”+
-