-
2 Kíróníkà 7:19-22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Àmọ́ tí ẹ bá pa dà lẹ́yìn mi, tí ẹ kò sì pa àwọn òfin àti àṣẹ tí mo fún yín mọ́, tí ẹ wá lọ ń sin àwọn ọlọ́run míì, tí ẹ sì ń forí balẹ̀ fún wọn,+ 20 ńṣe ni màá fa Ísírẹ́lì tu lórí ilẹ̀ mi tí mo fún wọn,+ màá gbé ilé yìí tí mo yà sí mímọ́ fún orúkọ mi sọ nù kúrò níwájú mi, màá sọ ọ́ di ohun ẹ̀gàn* àti ohun ẹ̀sín láàárín gbogbo èèyàn.+ 21 Ilé yìí á di àwókù. Gbogbo ẹni tó bá gba ibẹ̀ kọjá á wò ó tìyanutìyanu,+ á sì sọ pé, ‘Kì nìdí tí Jèhófà fi ṣe báyìí sí ilẹ̀ yìí àti sí ilé yìí?’+ 22 Nígbà náà, wọ́n á sọ pé, ‘Torí pé wọ́n fi Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn sílẹ̀ ni,+ ẹni tó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ wọ́n yíjú sí àwọn ọlọ́run míì, wọ́n ń forí balẹ̀ fún wọn,+ wọ́n sì ń sìn wọ́n. Ìdí nìyẹn tó fi mú gbogbo àjálù yìí bá wọn.’”+
-