-
1 Àwọn Ọba 9:6-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Àmọ́ tí ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín bá pa dà lẹ́yìn mi, tí ẹ kò sì pa àwọn àṣẹ àti òfin tí mo fún yín mọ́, tí ẹ wá lọ ń sin àwọn ọlọ́run míì, tí ẹ sì ń forí balẹ̀ fún wọn,+ 7 ṣe ni màá ké Ísírẹ́lì kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fún wọn,+ màá gbé ilé tí mo ti yà sí mímọ́ fún orúkọ mi sọ nù kúrò níwájú mi,+ Ísírẹ́lì yóò sì di ẹni ẹ̀gàn* àti ẹni ẹ̀sín láàárín gbogbo èèyàn.+ 8 Ilé yìí á di àwókù.+ Gbogbo ẹni tó bá gba ibẹ̀ kọjá á wò ó tìyanutìyanu, á súfèé, á sì sọ pé, ‘Kì nìdí tí Jèhófà fi ṣe báyìí sí ilẹ̀ yìí àti sí ilé yìí?’+ 9 Nígbà náà, wọ́n á sọ pé, ‘Torí pé wọ́n fi Jèhófà Ọlọ́run wọn sílẹ̀ ni, ẹni tó mú àwọn baba ńlá wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, wọ́n yíjú sí àwọn ọlọ́run míì, wọ́n ń forí balẹ̀ fún wọn, wọ́n sì ń sìn wọ́n. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi mú gbogbo àjálù yìí bá wọn.’”+
-