29 Nítorí náà, jẹ́ kí ó dùn mọ́ ọ nínú láti bù kún ilé ìránṣẹ́ rẹ, sì jẹ́ kí ó máa wà títí láé níwájú rẹ;+ nítorí ìwọ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti ṣèlérí, sì jẹ́ kí ìbùkún rẹ máa wà lórí ilé ìránṣẹ́ rẹ títí láé.”+
4 Àmọ́, nítorí Dáfídì,+ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ jẹ́ kí àtọmọdọ́mọ rẹ̀ máa ṣàkóso* ní Jerúsálẹ́mù,+ ó gbé ọmọ rẹ̀ dìde lẹ́yìn rẹ̀, ó sì jẹ́ kí Jerúsálẹ́mù máa wà nìṣó.