-
Àwọn Onídàájọ́ 9:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Nígbà tó yá, Ábímélékì+ ọmọ Jerubáálì lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin ìyá rẹ̀ ní Ṣékémù, ó sì sọ fún àwọn àti gbogbo ìdílé bàbá rẹ̀ àgbà* pé: 2 “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ bi gbogbo àwọn olórí* ní Ṣékémù pé, ‘Èwo ló dáa jù fún yín, pé kí gbogbo àádọ́rin (70) ọmọkùnrin Jerubáálì+ máa jọba lé yín lórí àbí kí ọkùnrin kan ṣoṣo máa jọba lé yín lórí? Ẹ má gbàgbé pé ẹ̀jẹ̀ kan náà ni wá.’”*
-