-
1 Àwọn Ọba 2:31-34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
31 Ni ọba bá sọ fún un pé: “Ohun tí ó sọ ni kí o ṣe; ṣá a balẹ̀, kí o sin ín, kí o sì mú ẹ̀jẹ̀ tí Jóábù ta sílẹ̀ láìyẹ+ kúrò lórí mi àti kúrò lórí ilé bàbá mi. 32 Jèhófà yóò mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sórí rẹ̀, nítorí ó fi idà ṣá àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n lóòótọ́ jù ú lọ balẹ̀, tí wọ́n sì dára jù ú, ó pa wọ́n láìjẹ́ kí Dáfídì bàbá mi mọ̀. Àwọn ọkùnrin náà ni: Ábínérì+ ọmọ Nérì, olórí ọmọ ogun Ísírẹ́lì+ àti Ámásà+ ọmọ Jétà, olórí ọmọ ogun Júdà.+ 33 Ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wá sórí Jóábù àti sórí àwọn ọmọ* rẹ̀ títí láé;+ àmọ́ kí àlàáfíà Jèhófà wà lórí Dáfídì àti àwọn ọmọ* rẹ̀, kí ó wà lórí ilé rẹ̀ àti ìtẹ́ rẹ̀ títí láé.” 34 Ìgbà náà ni Bẹnáyà ọmọ Jèhóádà lọ ṣá Jóábù balẹ̀, ó pa á, wọ́n sì sin ín sí ilé rẹ̀ ní aginjù.
-