17 “Àmọ́ tí ọkàn yín bá yí pa dà,+ tí ẹ ò fetí sílẹ̀, tí ẹ sì jẹ́ kí ọkàn yín fà sí àwọn ọlọ́run míì, tí ẹ wá ń forí balẹ̀ fún wọn, tí ẹ sì ń sìn wọ́n,+ 18 mò ń sọ fún yín lónìí pé ó dájú pé ẹ máa ṣègbé.+ Ẹ̀mí yín ò sì ní gùn lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń sọdá Jọ́dánì lọ gbà.