-
Léfítíkù 18:24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 “‘Ẹ má fi èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan yìí sọ ara yín di aláìmọ́, torí gbogbo àwọn nǹkan yìí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí mo fẹ́ lé kúrò níwájú yín fi sọ ara wọn di aláìmọ́.+
-
-
Diutarónómì 12:30, 31Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 rí i pé o ò kó sí ìdẹkùn lẹ́yìn tí wọ́n bá pa run kúrò níwájú rẹ. Má ṣe béèrè nípa àwọn ọlọ́run wọn pé, ‘Báwo ni àwọn orílẹ̀-èdè yìí ṣe máa ń sin àwọn ọlọ́run wọn? Ohun tí wọ́n ṣe lèmi náà máa ṣe.’+ 31 O ò gbọ́dọ̀ ṣe báyìí sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ, torí gbogbo ohun tí Jèhófà kórìíra ni wọ́n máa ń ṣe sí àwọn ọlọ́run wọn, kódà wọ́n máa ń sun àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn nínú iná sí àwọn ọlọ́run wọn.+
-
-
Diutarónómì 18:9-11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 “Tí ẹ bá ti dé ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún yín, ẹ ò gbọ́dọ̀ bá àwọn orílẹ̀-èdè yẹn ṣe àwọn ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe.+ 10 Ẹnì kankan láàárín yín ò gbọ́dọ̀ sun ọmọkùnrin rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ nínú iná,+ kò gbọ́dọ̀ woṣẹ́,+ kò gbọ́dọ̀ pidán,+ kò gbọ́dọ̀ wá àmì ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀,+ kò gbọ́dọ̀ di oṣó,+ 11 kò gbọ́dọ̀ fi èèdì di àwọn ẹlòmíì, kò gbọ́dọ̀ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò+ tàbí woṣẹ́woṣẹ́,+ kò sì gbọ́dọ̀ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ òkú.+
-