-
Diutarónómì 15:7, 8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 “Tí ọ̀kan lára àwọn arákùnrin rẹ bá di aláìní láàárín rẹ nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú rẹ ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ, o ò gbọ́dọ̀ mú kí ọkàn rẹ le tàbí kí o háwọ́ sí arákùnrin rẹ tó jẹ́ aláìní.+ 8 Ṣe ni kí o lawọ́ sí i,+ kí o sì rí i dájú pé o yá a ní* ohunkóhun tó bá nílò tàbí tó ń jẹ ẹ́ níyà.
-
-
Jeremáyà 34:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Jeremáyà sọ nìyí, lẹ́yìn tí Ọba Sedekáyà bá gbogbo èèyàn tó wà ní Jerúsálẹ́mù dá májẹ̀mú láti kéde òmìnira fún wọn,+ 9 pé kí kálukú wọn dá àwọn ẹrú wọn tó jẹ́ Hébérù sílẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, kí ẹnikẹ́ni má bàa fi Júù bíi tirẹ̀ ṣe ẹrú.
-