6 Kí ẹ rí i pé ẹ̀ ń pa wọ́n mọ́,+ torí èyí máa fi hàn pé ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n+ àti olóye+ lójú àwọn èèyàn tó máa gbọ́ nípa gbogbo ìlànà yìí, wọ́n á sì sọ pé, ‘Ó dájú pé ọlọ́gbọ́n àti olóye ni àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ńlá yìí.’+
20 Nítorí àwọn ànímọ́* rẹ̀ tí kò ṣeé fojú rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, torí à ń fi òye mọ̀ wọ́n látinú àwọn ohun tó dá,+ títí kan agbára ayérayé tó ní+ àti bó ṣe jẹ́ Ọlọ́run,+ tó fi jẹ́ pé wọn ò ní àwíjàre.