ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 4:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Kí ẹ rí i pé ẹ̀ ń pa wọ́n mọ́,+ torí èyí máa fi hàn pé ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n+ àti olóye+ lójú àwọn èèyàn tó máa gbọ́ nípa gbogbo ìlànà yìí, wọ́n á sì sọ pé, ‘Ó dájú pé ọlọ́gbọ́n àti olóye ni àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ńlá yìí.’+

  • Jóṣúà 1:7, 8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 “Ṣáà rí i pé o jẹ́ onígboyà àti alágbára gidigidi, kí o sì rí i pé ò ń tẹ̀ lé gbogbo Òfin tí Mósè ìránṣẹ́ mi pa láṣẹ fún ọ. Má yà kúrò nínú rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì,+ kí o lè máa hùwà ọgbọ́n níbikíbi tí o bá lọ.+ 8 Ìwé Òfin yìí kò gbọ́dọ̀ kúrò ní ẹnu rẹ,+ kí o máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kà á* tọ̀sántòru, kí o lè rí i pé ò ń tẹ̀ lé gbogbo ohun tí wọ́n kọ sínú rẹ̀;+ ìgbà yẹn ni ọ̀nà rẹ máa yọrí sí rere, tí wàá sì máa hùwà ọgbọ́n.+

  • 1 Àwọn Ọba 2:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 Máa ṣe ohun tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní kí o ṣe, kí o máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀, kí o máa pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ àti àwọn àṣẹ rẹ̀, àwọn ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìránnilétí rẹ̀, bí wọ́n ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin Mósè;+ ìgbà náà ni wàá ṣàṣeyọrí* nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe àti níbikíbi tí o bá yíjú sí.

  • Sáàmù 119:100
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 100 Mò ń fi òye hùwà ju àwọn àgbààgbà lọ,

      Nítorí pé mò ń pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́.

  • 2 Tímótì 3:14, 15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Àmọ́ kí ìwọ má ṣe fi àwọn nǹkan tí o ti kọ́ sílẹ̀, tí a sì mú kí o gbà gbọ́,*+ o sì mọ ọ̀dọ̀ àwọn tí o ti kọ́ wọn 15 àti pé láti kékeré jòjòló  + lo ti mọ ìwé mímọ́,+ èyí tó lè mú kí o di ọlọ́gbọ́n kí o lè rí ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jésù.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́