9 Kí ló dé tí o kò fi ka ọ̀rọ̀ Jèhófà sí, tí o wá ṣe ohun tó burú lójú rẹ̀? O fi idà pa+ Ùráyà ọmọ Hétì! Lẹ́yìn náà, o sọ ìyàwó rẹ̀ di tìrẹ+ lẹ́yìn tí o ti mú kí idà àwọn ọmọ Ámónì pa á.+
11 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Wò ó, màá mú kí àjálù bá ọ láti inú ilé ara rẹ;+ ojú rẹ ni màá ti gba àwọn ìyàwó rẹ,+ tí màá fi wọ́n fún ọkùnrin míì,* tí á sì bá wọn sùn ní ọ̀sán gangan.*+