ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 6:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 Jèhófà wá rí i pé ìwà burúkú èèyàn pọ̀ gan-an ní ayé, ó sì rí i pé kìkì ohun búburú ló ń rò lọ́kàn ní gbogbo ìgbà.+

  • 2 Kíróníkà 16:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Nítorí ojú Jèhófà ń lọ káàkiri gbogbo ayé+ láti fi agbára* rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín.+ O ti hùwà òmùgọ̀ lórí ọ̀ràn yìí; láti ìsinsìnyí lọ, ogun yóò máa jà ọ́.”+

  • Jóòbù 31:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 Ṣebí ó ń rí àwọn ọ̀nà mi,+

      Tó sì ń ka gbogbo ìṣísẹ̀ mi?

  • Òwe 5:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 Nítorí àwọn ọ̀nà èèyàn wà níwájú Jèhófà;

      Ó ń ṣàyẹ̀wò gbogbo ipa ọ̀nà rẹ̀.+

  • Òwe 15:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  3 Ojú Jèhófà wà níbi gbogbo,

      Ó ń ṣọ́ ẹni burúkú àti ẹni rere.+

  • Jeremáyà 16:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Nítorí ojú mi wà lára gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe.*

      Wọn ò pa mọ́ lójú mi,

      Bẹ́ẹ̀ ni àṣìṣe wọn kò ṣókùnkùn sí mi.

  • Jeremáyà 32:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Ìpinnu rẹ* ga, àwọn iṣẹ́ rẹ sì tóbi,+ ìwọ tí ojú rẹ ń wo gbogbo ọ̀nà àwọn èèyàn,+ láti san èrè fún ẹnì kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ṣe.+

  • 1 Pétérù 3:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Nítorí ojú Jèhófà* wà lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn;+ àmọ́ Jèhófà* kọjú ìjà sí àwọn tó ń ṣe ohun búburú.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́