2 Kíróníkà 16:9 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 9 Nítorí ojú Jèhófà ń lọ káàkiri gbogbo ayé+ láti fi agbára* rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín.+ O ti hùwà òmùgọ̀ lórí ọ̀ràn yìí; láti ìsinsìnyí lọ, ogun yóò máa jà ọ́.”+ Sáàmù 11:4 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 4 Jèhófà wà nínú tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ̀.+ Ìtẹ́ Jèhófà wà ní ọ̀run.+ Ojú rẹ̀ ń wò, ojú rẹ̀ tó rí ohun gbogbo* ń ṣàyẹ̀wò àwọn ọmọ èèyàn.+ Sáàmù 17:3 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 3 O ti ṣàyẹ̀wò ọkàn mi, o ti bẹ̀ mí wò ní òru;+O ti yọ́ mi mọ́;+Wàá rí i pé mi ò ní èrò ibi kankan lọ́kàn,Ẹnu mi kò sì dẹ́ṣẹ̀. Jeremáyà 17:10 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 10 Èmi, Jèhófà, ń wá inú ọkàn,+Mo sì ń ṣàyẹ̀wò èrò inú,*Kí n lè san èrè fún ẹnì kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀Àti gẹ́gẹ́ bí èso iṣẹ́ rẹ̀.+ Hébérù 4:13 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 13 Kò sí ìṣẹ̀dá kankan tó fara pa mọ́ ní ojú rẹ̀,+ àmọ́ ohun gbogbo wà ní ìhòòhò, ó sì wà ní gbangba lójú ẹni tí a gbọ́dọ̀ jíhìn fún.+
9 Nítorí ojú Jèhófà ń lọ káàkiri gbogbo ayé+ láti fi agbára* rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín.+ O ti hùwà òmùgọ̀ lórí ọ̀ràn yìí; láti ìsinsìnyí lọ, ogun yóò máa jà ọ́.”+
4 Jèhófà wà nínú tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ̀.+ Ìtẹ́ Jèhófà wà ní ọ̀run.+ Ojú rẹ̀ ń wò, ojú rẹ̀ tó rí ohun gbogbo* ń ṣàyẹ̀wò àwọn ọmọ èèyàn.+
3 O ti ṣàyẹ̀wò ọkàn mi, o ti bẹ̀ mí wò ní òru;+O ti yọ́ mi mọ́;+Wàá rí i pé mi ò ní èrò ibi kankan lọ́kàn,Ẹnu mi kò sì dẹ́ṣẹ̀.
10 Èmi, Jèhófà, ń wá inú ọkàn,+Mo sì ń ṣàyẹ̀wò èrò inú,*Kí n lè san èrè fún ẹnì kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀Àti gẹ́gẹ́ bí èso iṣẹ́ rẹ̀.+
13 Kò sí ìṣẹ̀dá kankan tó fara pa mọ́ ní ojú rẹ̀,+ àmọ́ ohun gbogbo wà ní ìhòòhò, ó sì wà ní gbangba lójú ẹni tí a gbọ́dọ̀ jíhìn fún.+