5 Má bẹ̀rù, torí mo wà pẹ̀lú rẹ.+
Màá mú ọmọ rẹ wá láti ìlà oòrùn,
Màá sì kó ọ jọ láti ìwọ̀ oòrùn.+
 6 Màá sọ fún àríwá pé, ‘Dá wọn sílẹ̀!’+
Màá sì sọ fún gúúsù pé, ‘Má ṣe dá wọn dúró.
Mú àwọn ọmọkùnrin mi wá láti ọ̀nà jíjìn àti àwọn ọmọbìnrin mi láti àwọn ìkángun ayé,+
                                        
                                    
								                            
                        
						                    
									            
		            
				
                                            - 
	                        
            
            
    
            
                
                    Jeremáyà 31:8
                 
                    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
                 
 
- 
                            
								
								                                    - 
                                        
											 8 Màá mú wọn pa dà wá láti ilẹ̀ àríwá.+ Màá sì kó wọn jọ láti ibi tó jìnnà jù lọ láyé.+ Àwọn afọ́jú àti àwọn arọ máa wà lára wọn,+ Aboyún àti ẹni tó ń rọbí, gbogbo wọn pa pọ̀. 
Bí ìjọ ńlá ni wọ́n máa pa dà sí ibí yìí.+