-
Ẹ́sírà 7:27, 28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa, ẹni tó fi sí ọba lọ́kàn láti ṣe ilé Jèhófà tó wà ní Jerúsálẹ́mù lọ́ṣọ̀ọ́!+ 28 Ó ti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi níwájú ọba+ àti àwọn agbani-nímọ̀ràn rẹ̀+ àti níwájú gbogbo àwọn ìjòyè ọba tí wọ́n jẹ́ alágbára. Torí náà, mo mọ́kàn le* nítorí ọwọ́ Jèhófà Ọlọ́run mi wà lára mi, mo sì kó àwọn aṣáájú ọkùnrin* jọ látinú Ísírẹ́lì kí wọ́n lè bá mi lọ.
-