3 “Ìgbà náà ni màá kó àwọn tó ṣẹ́ kù lára àgùntàn mi jọ láti gbogbo ilẹ̀ tí mo fọ́n wọn ká sí,+ màá sì mú wọn pa dà wá sí ibi ìjẹko wọn,+ wọ́n á máa bímọ, wọ́n á sì di púpọ̀.+
12 Èmi yóò bójú tó àwọn àgùntàn mi bí olùṣọ́ àgùntàn tó rí àwọn àgùntàn rẹ̀ tó fọ́n ká, tó sì ń fún wọn ní oúnjẹ.+ Èmi yóò gbà wọ́n sílẹ̀ kúrò ní gbogbo ibi tí wọ́n fọ́n ká sí ní ọjọ́ ìkùukùu* àti ìṣúdùdù tó kàmàmà.+