11 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà tún máa na ọwọ́ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì, láti gba àṣẹ́kù àwọn èèyàn rẹ̀ pa dà, àwọn tó ṣẹ́ kù láti Ásíríà,+ Íjíbítì,+ Pátírọ́sì,+ Kúṣì,+ Élámù,+ Ṣínárì,* Hámátì àti àwọn erékùṣù òkun.+
14 Màá sì jẹ́ kí ẹ rí mi,’+ ni Jèhófà wí. ‘Màá kó yín pa dà láti oko ẹrú, màá sì kó yín jọ láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè àti gbogbo ibi tí mo fọ́n yín ká sí,’+ ni Jèhófà wí. ‘Màá sì mú yín pa dà wá sí ibi tí mo ti jẹ́ kí wọ́n kó yín lọ sí ìgbèkùn.’+