ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Sámúẹ́lì 11:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Lẹ́yìn náà, Dáfídì ní kí àwọn òjíṣẹ́ lọ mú un wá.+ Torí náà, ó wọlé wá bá a, ó sì bá a sùn.+ (Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà tí obìnrin náà ń wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ohun àìmọ́*+ rẹ̀.) Lẹ́yìn náà, ó pa dà sílé rẹ̀.

  • 2 Sámúẹ́lì 12:10, 11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Wò ó, idà kò ní kúrò ní ilé rẹ láé,+ nítorí pé o kọ̀ mí, tí o sì sọ ìyàwó Ùráyà ọmọ Hétì di tìrẹ.’ 11 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Wò ó, màá mú kí àjálù bá ọ láti inú ilé ara rẹ;+ ojú rẹ ni màá ti gba àwọn ìyàwó rẹ,+ tí màá fi wọ́n fún ọkùnrin míì,* tí á sì bá wọn sùn ní ọ̀sán gangan.*+

  • Òwe 6:32-35
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 32 Ẹni tó bá bá obìnrin ṣe àgbèrè kò ní làákàyè;*

      Ẹni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ ń fa ìparun bá ara* rẹ̀.+

      33 Ọgbẹ́ àti àbùkù ló máa gbà,+

      Ìtìjú rẹ̀ kò sì ní pa rẹ́.+

      34 Nítorí owú máa ń mú kí ọkọ bínú;

      Kò ní ṣojú àánú nígbà tó bá ń gbẹ̀san.+

      35 Kò ní gba àsandípò;*

      Láìka bí ẹ̀bùn náà ṣe pọ̀ tó, kò ní tù ú lójú.

  • Hébérù 13:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo èèyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó má sì ní ẹ̀gbin,+ torí Ọlọ́run máa dá àwọn oníṣekúṣe* àti àwọn alágbèrè lẹ́jọ́.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́