-
1 Àwọn Ọba 2:22-24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Ni Ọba Sólómọ́nì bá dá ìyá rẹ̀ lóhùn pé: “Kí ló dé tí o fi ní kí n fún Ádóníjà ní Ábíṣágì ará Ṣúnémù? Ò bá kúkú ní kí n fún un ní ìjọba pẹ̀lú+ nítorí pé ẹ̀gbọ́n mi ni,+ ẹ̀yìn rẹ̀ sì ni àlùfáà Ábíátárì àti Jóábù+ ọmọ Seruáyà+ wà.”
23 Ni Ọba Sólómọ́nì bá fi Jèhófà búra pé: “Kí Ọlọ́run fìyà jẹ mí gan-an, tí kò bá jẹ́ pé ohun tó máa gbẹ̀mí* Ádóníjà ló ń béèrè yìí. 24 Ní báyìí, bí Jèhófà ti wà láàyè, ẹni tí ó fìdí mi múlẹ̀ gbọn-in,+ tí ó mú mi jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì bàbá mi, tí ó sì kọ́ ilé fún mi*+ bí ó ti ṣèlérí, òní ni a ó pa Ádóníjà.”+
-