ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 19:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 “‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ yí ìdájọ́ po. Ẹ ò gbọ́dọ̀ rẹ́ aláìní jẹ tàbí kí ẹ ṣe ojúsàájú sí ọlọ́rọ̀.+ Máa ṣe ìdájọ́ òdodo tí o bá ń dá ẹjọ́ ẹnì kejì rẹ.

  • Diutarónómì 1:16, 17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 “Nígbà yẹn, mo sọ fún àwọn onídàájọ́ yín pé, ‘Tí ẹ bá ń gbọ́ ẹjọ́ láàárín àwọn arákùnrin yín, kí ẹ máa fi òdodo ṣèdájọ́+ láàárín ọkùnrin kan àti arákùnrin rẹ̀ tàbí àjèjì tí ẹ jọ ń gbé.+ 17 Ẹ ò gbọ́dọ̀ gbè sápá kan nínú ìdájọ́.+ Bí ẹ ṣe máa gbọ́ ẹjọ́ ẹni tó kéré ni kí ẹ ṣe gbọ́ ti ẹni ńlá.+ Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn èèyàn dẹ́rù bà yín,+ torí Ọlọ́run ló ni ìdájọ́;+ tí ẹjọ́ kan bá sì le jù fún yín, kí ẹ gbé e wá sọ́dọ̀ mi, màá sì gbọ́ ọ.’+

  • Diutarónómì 16:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 O ò gbọ́dọ̀ ṣe èrú tí o bá ń dájọ́,+ o ò gbọ́dọ̀ ṣe ojúsàájú,+ o ò sì gbọ́dọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, torí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ máa ń dí ọlọ́gbọ́n lójú,+ ó sì máa ń mú kí olódodo yí ọ̀rọ̀ po.

  • 2 Kíróníkà 19:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Ẹ jẹ́ kí ìbẹ̀rù Jèhófà wà lọ́kàn yín.+ Ẹ máa kíyè sára nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe, nítorí pé kò sí àìṣẹ̀tọ́,+ kò sí ojúsàájú,+ bẹ́ẹ̀ ni kò sí gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa.”+

  • 1 Tímótì 5:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 Mo pàṣẹ tó rinlẹ̀ yìí fún ọ níwájú Ọlọ́run àti Kristi Jésù àti àwọn áńgẹ́lì àyànfẹ́ pé kí o máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí láìṣe ẹ̀tanú tàbí ojúsàájú.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́