Sáàmù 141:5 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 5 Tí olódodo bá gbá mi, á jẹ́ pé ó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí mi;+Tó bá bá mi wí, á dà bí òróró ní orí mi,+Tí orí mi kò ní kọ̀ láé.+ Mi ò ní dákẹ́ àdúrà kódà nígbà tí àjálù bá bá wọn. Òwe 1:8, 9 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 8 Ọmọ mi, fetí sí ìbáwí bàbá rẹ,+Má sì pa ẹ̀kọ́* ìyá rẹ tì.+ 9 Wọ́n dà bí adé ẹwà fún orí rẹ+Àti ohun ọ̀ṣọ́ tó rẹwà fún ọrùn rẹ.+ Òwe 9:8 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 8 Má ṣe bá afiniṣẹ̀sín wí, torí á kórìíra rẹ.+ Bá ọlọ́gbọ́n wí, yóò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ.+
5 Tí olódodo bá gbá mi, á jẹ́ pé ó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí mi;+Tó bá bá mi wí, á dà bí òróró ní orí mi,+Tí orí mi kò ní kọ̀ láé.+ Mi ò ní dákẹ́ àdúrà kódà nígbà tí àjálù bá bá wọn.
8 Ọmọ mi, fetí sí ìbáwí bàbá rẹ,+Má sì pa ẹ̀kọ́* ìyá rẹ tì.+ 9 Wọ́n dà bí adé ẹwà fún orí rẹ+Àti ohun ọ̀ṣọ́ tó rẹwà fún ọrùn rẹ.+