-
Ẹ́kísódù 23:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Tí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹni tó kórìíra rẹ, tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ṣubú tí kò sì lè dìde torí ẹrù tó gbé, o ò gbọ́dọ̀ fi sílẹ̀ lọ. Kí o bá a gbé ẹrù náà kúrò.+
-
-
2 Àwọn Ọba 6:21, 22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Nígbà tí ọba Ísírẹ́lì rí wọn, ó sọ fún Èlíṣà pé: “Ṣé kí n pa wọ́n, ṣé kí n pa wọ́n, bàbá mi?” 22 Àmọ́, ó sọ pé: “O ò gbọ́dọ̀ pa wọ́n. Ṣé o máa ń pa àwọn tí o fi idà rẹ àti ọrun rẹ mú lẹ́rú ni? Ṣe ni kí o fún wọn ní oúnjẹ àti omi, kí wọ́n lè jẹ, kí wọ́n mu,+ kí wọ́n sì pa dà sọ́dọ̀ olúwa wọn.”
-
-
Òwe 24:17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú, má ṣe dunnú,
Tó bá sì kọsẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ yọ̀;+
-