-
1 Àwọn Ọba 17:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Nígbà náà, Èlíjà*+ ará Tíṣíbè, tó ń gbé ní Gílíádì+ sọ fún Áhábù pé: “Bí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì tí mò ń sìn* ti wà láàyè, kò ní sí òjò tàbí ìrì ní àwọn ọdún tó ń bọ̀, àfi nípa ọ̀rọ̀ mi!”+
2 Jèhófà bá a sọ̀rọ̀, ó ní: 3 “Kúrò ní ibí yìí, kí o forí lé ìlà oòrùn, kí o sì fara pa mọ́ sí Àfonífojì Kérítì, tó wà ní ìlà oòrùn Jọ́dánì.
-
-
Òwe 29:2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Nígbà tí olódodo bá pọ̀, àwọn èèyàn á máa yọ̀,
Àmọ́ tí ẹni burúkú bá ń ṣàkóso, àwọn èèyàn á máa kérora.+
-