ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Àwọn Ọba 17:15, 16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Nítorí náà, ó lọ, ó sì ṣe ohun tí Èlíjà sọ, ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni obìnrin náà àti agbo ilé rẹ̀ pẹ̀lú Èlíjà fi rí oúnjẹ jẹ.+ 16 Ìyẹ̀fun kò tán nínú ìkòkò náà, òróró kò sì gbẹ nínú ìṣà kékeré náà, bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Èlíjà sọ.

  • 1 Àwọn Ọba 17:22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Jèhófà gbọ́ ẹ̀bẹ̀ Èlíjà,+ ẹ̀mí* ọmọ náà sọ jí, ó sì yè.+

  • 1 Àwọn Ọba 17:24
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 Obìnrin náà wá sọ fún Èlíjà pé: “Mo ti wá mọ̀ báyìí pé èèyàn Ọlọ́run+ ni ọ́ lóòótọ́ àti pé ọ̀rọ̀ Jèhófà tó wà lẹ́nu rẹ jẹ́ òótọ́.”

  • 1 Àwọn Ọba 18:36
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 36 Ní déédéé àkókò tí wọ́n máa ń fi ọrẹ ọkà ìrọ̀lẹ́ rúbọ,+ wòlíì Èlíjà wá síwájú, ó sì sọ pé: “Jèhófà, Ọlọ́run Ábúráhámù,+ Ísákì+ àti Ísírẹ́lì, jẹ́ kí wọ́n mọ̀ lónìí pé ìwọ ni Ọlọ́run Ísírẹ́lì àti pé ìránṣẹ́ rẹ ni mí, kí wọ́n sì mọ̀ pé ìwọ lo ní kí n ṣe gbogbo nǹkan yìí.+

  • 1 Àwọn Ọba 18:38
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 38 Ni iná Jèhófà bá bọ́ láti òkè, ó sì jó ẹran ẹbọ sísun+ náà àti àwọn igi, àwọn òkúta àti iyẹ̀pẹ̀ ibẹ̀ run, ó sì lá omi inú kòtò náà gbẹ.+

  • 1 Àwọn Ọba 18:46
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 46 Àmọ́, Jèhófà fún Èlíjà lágbára, ó wé* aṣọ rẹ̀ mọ́ ìbàdí, ó sì ń sáré lọ níwájú Áhábù títí dé Jésírẹ́lì.

  • 2 Àwọn Ọba 2:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Nígbà náà, Èlíjà mú ẹ̀wù oyè rẹ̀,+ ó ká a, ó sì lu omi náà, ó pín sápá ọ̀tún àti sápá òsì, tó fi jẹ́ pé àwọn méjèèjì gba orí ilẹ̀ gbígbẹ sọdá.+

  • 2 Àwọn Ọba 2:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Bí wọ́n ṣe ń rìn lọ, wọ́n ń sọ̀rọ̀, lójijì kẹ̀kẹ́ ẹṣin oníná àti àwọn ẹṣin oníná+ ya àwọn méjèèjì sọ́tọ̀, ìjì sì gbé Èlíjà lọ sí ọ̀run.*+

  • Lúùkù 1:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Bákan náà, ó máa lọ ṣáájú rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí àti agbára Èlíjà,+ kó lè yí ọkàn àwọn bàbá pa dà sí àwọn ọmọ+ àti àwọn aláìgbọràn sí ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ ti àwọn olódodo, kó lè ṣètò àwọn èèyàn tí a ti múra sílẹ̀ fún Jèhófà.”*+

  • Jòhánù 1:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Ẹ̀rí tí Jòhánù jẹ́ nìyí nígbà tí àwọn Júù rán àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì láti Jerúsálẹ́mù kí wọ́n lọ bi í pé: “Ta ni ọ́?”+

  • Jòhánù 1:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 Wọ́n bi í pé: “Ta wá ni ọ́? Ṣé ìwọ ni Èlíjà?”+ Ó dáhùn pé: “Èmi kọ́.” “Ṣé ìwọ ni Wòlíì náà?”+ Ó dáhùn pé: “Rárá!”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́