ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 39:5, 6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  5 Lóòótọ́, o ti mú kí ọjọ́ ayé mi kéré;*+

      Gbogbo ọjọ́ ayé mi kò sì jẹ́ nǹkan kan lójú rẹ.+

      Ní ti ọmọ èèyàn, bó tilẹ̀ dà bíi pé kò sí nínú ewu, bí èémí lásán ló rí.+ (Sélà)

       6 Dájúdájú, bí òjìji ni ọmọ èèyàn ń rìn kiri.

      Ó ń sáré kiri* lórí òfo.

      Ó ń kó ọrọ̀ jọ pelemọ láìmọ ẹni tó máa gbádùn rẹ̀.+

  • Oníwàásù 2:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Àmọ́ nígbà tí mo ronú lórí gbogbo iṣẹ́ tí ọwọ́ mi ti ṣe àti gbogbo iṣẹ́ àṣekára tí mo ti sapá láti ṣe yọrí,+ mo rí i pé asán ni gbogbo rẹ̀, ìmúlẹ̀mófo;*+ kò sí ohun gidi kan* lábẹ́ ọ̀run.*+

  • Oníwàásù 2:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Mo wá kórìíra gbogbo iṣẹ́ àṣekára tí mo ti ṣe lábẹ́ ọ̀run,*+ torí mo gbọ́dọ̀ fi í sílẹ̀ fún ẹni tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi.+

  • Oníwàásù 2:26
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 26 Ọlọ́run ń fún ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ àti ìdùnnú,+ àmọ́ ó ń fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní iṣẹ́ kíkó jọ àti ṣíṣà jọ kí wọ́n lè fún ẹni tó ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tòótọ́.+ Asán ni èyí pẹ̀lú, ìmúlẹ̀mófo* sì ni.

  • Lúùkù 12:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀, kí ẹ sì máa ṣọ́ra fún onírúurú ojúkòkòrò,*+ torí pé tí ẹnì kan bá tiẹ̀ ní nǹkan rẹpẹtẹ, àwọn ohun tó ní kò lè fún un ní ìwàláàyè.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́