ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́sítà 8:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Ní gbogbo ìpínlẹ̀* àti gbogbo ìlú tí àṣẹ ọba àti òfin rẹ̀ dé, àwọn Júù ń yọ̀, inú wọn ń dùn, wọ́n ń se àsè, wọ́n sì ń ṣe àjọyọ̀. Ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn ilẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí í pe ara wọn ní Júù,+ torí ẹ̀rù àwọn Júù ń bà wọ́n.

  • Àìsáyà 14:1, 2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Torí Jèhófà máa ṣàánú Jékọ́bù,+ ó sì máa tún Ísírẹ́lì yàn.+ Ó máa mú kí wọ́n gbé* ní ilẹ̀ wọn,+ àwọn àjèjì máa dara pọ̀ mọ́ wọn, wọ́n sì máa sọ ara wọn di ará ilé Jékọ́bù.+ 2 Àwọn èèyàn máa mú wọn, wọ́n á mú wọn wá sí àyè wọn, ilé Ísírẹ́lì sì máa fi wọ́n ṣe ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin+ ní ilẹ̀ Jèhófà; wọ́n máa mú àwọn tó mú wọn lẹ́rú, wọ́n sì máa di olórí àwọn tó fipá kó wọn ṣiṣẹ́.

  • Àìsáyà 49:23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 23 Àwọn ọba máa di olùtọ́jú rẹ,+

      Àwọn ọmọ wọn obìnrin sì máa di alágbàtọ́ rẹ.

      Wọ́n máa tẹrí ba fún ọ, wọ́n á sì dojú bolẹ̀,+

      Wọ́n máa lá iyẹ̀pẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ,+

      Wàá sì mọ̀ pé èmi ni Jèhófà;

      Ojú ò ní ti àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé mi.”+

  • Àìsáyà 60:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Àwọn ọmọ àwọn tó fìyà jẹ ọ́ máa wá, wọ́n á sì tẹrí ba níwájú rẹ;

      Gbogbo àwọn tó ń hùwà àfojúdi sí ọ gbọ́dọ̀ tẹrí ba níbi ẹsẹ̀ rẹ,

      Wọ́n sì máa pè ọ́ ní ìlú Jèhófà,

      Síónì Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.+

  • Àìsáyà 61:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  5 “Àwọn àjèjì máa dúró, wọ́n sì máa tọ́jú àwọn agbo ẹran yín,

      Àwọn àlejò + máa jẹ́ àgbẹ̀ yín, wọ́n á sì máa bá yín rẹ́wọ́ àjàrà.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́