-
Sáàmù 72:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
72 Ọlọ́run, sọ àwọn ìdájọ́ rẹ fún ọba,
Kí o sì kọ́ ọmọ ọba ní òdodo rẹ.+
-
-
Àìsáyà 9:6, 7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
Orúkọ rẹ̀ á máa jẹ́ Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn,+ Ọlọ́run Alágbára,+ Baba Ayérayé, Ọmọ Aládé Àlàáfíà.
7 Àkóso* rẹ̀ á máa gbilẹ̀ títí lọ,
Àlàáfíà kò sì ní lópin,+
Lórí ìtẹ́ Dáfídì+ àti lórí ìjọba rẹ̀,
Kó lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in,+ kó sì gbé e ró,
Nípasẹ̀ ìdájọ́+ tí ó tọ́ àti òdodo,+
Láti ìsinsìnyí lọ àti títí láé.
Ìtara Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa ṣe èyí.
-